IROYIN YAJOYAJO

Monday, 4 September 2017

Opuro ni Ajimobi, ko fun mi nile kankan o - Ladoja


Gomina tele nipinle Oyo to tun je Osi Balogun tilu Ibadan, Oloye Rasidi Ladoja ti ni iro funfun balau ni oro kan ti Gomina Ajimobi so pe oun (Ajimobi) fun oun (Ladoja) ni pilooti ile kan laipe yii.
Eleyii ko seyin oro kan ti Gomina Ajimobi so lori telifisan lose to koja pe oun sese fun Ladoja ni pilooti Ile kan laipe yii ni.
Gege bi akowe iroyin Fun Ladoja, Latinwo se wi, egbe ilee Oloye Ladoja ninuu GRA ni ile ti won o tii ko nnkankan si ohun wa.
O ni kijoba  Ladoja gan an too de ori aleefa ni ile yii ti wa nibe  sugbon gege bii eni to ko akoyawo, ko so ile naa di tie rara.
O ni loorekoore ni Oloye Ladoja maa n sanko ori ile naa lati le je ko wa nimototo.
Laipe yii ni ileese to n ri si oro aato ilu ati ile kiko (Oyo state Housing corporation waa le iwe pe ijoba fee gbesele ile yen.
O ni idi niyii ti Ladoja fi ko leta sileese naa to si fi eda ranse si Gomina Ajimobi ninu eyi to ti so pe oun nife lati ra ile ohun.
Nigba ti Ajimobi ri leta naa lo so fawon ileese ohun pe ki won mase gbowo lowoo Ladoja, ki won fun un lofe.
Latinwo ni o waa je iyalenu fawon bi Ajimobi se n so bii enipe se lo mo on mo fun Ladoja ni Ile naa.

No comments:

Post a Comment