IROYIN YAJOYAJO

Monday, 4 September 2017

Awon odo o tii setan lati di Aare orileede yii - Obasanjo


Oloye Olusegun Obasanjo, eni to ti je Aare orileede yii nigba meji otooto ti so pe oun ko tii ri imurasile kankan lara awon odo orileede yii ti won n lakaka lati de ipo aare.
Nibi eto kan tawon odo gbekale lati sayeye ayajo ojo odo ti odun yii eleyii to waye nilu Abeokuta ni Obasanjo ti soro naa.
O ni enikeni to ba fee je aare lorileede yii gbodo ni imo kikun nipa tara ati nipa temi. O ni eko ihuwasi se pataki fun odo to ba fee solori eleyii to ni o sowon laarin awon odo asiko yii.
Obasanjo fi kun oro re pe ko nilo ki odo to ba ni nnkan se duro de ogoji odun lati dari orileede yii, o gbodo ti maa bere pelu jije olooto ati akinkanju lagbegbe re, kawon eeyan si ti maa ri iwa agba lara e.
O ni "Latoke lemi ti bere oselu mi, sugbon o ni awon igbese ti mo ti gbe nigba ti mo wa ni odo to ran mi lowo. Ko seni to maa yan yin, eyin le maa yan araa yin.
"Kilode tee fee di aare lomo ogoji odun, ki lo n da yin duro lati di aare lomo odun marundinlogoji tabi ogbon odun?"
Obasanjo waa ro gbogbo awon odo orileede yii lati ji giri, ki won si le awon agbalagba kuro nipo oselu orileede yii bere lati ile igbimo asofin ipinle titi depo aare.

No comments:

Post a Comment