Erin arintakiti lawon eeyan ti won wa nile ejoo majistreeti kan nilu Eko n rin nigba ti omokunrin eni odun mejilelogbon ti won fesun kan pe o fipa ba omo odun mejo sun so pe iro ni won pa mo oun nitori pe dokita ti so foun pe nnkan omokunrin oun ko lagbara.
Bayonne Lekan ni agbejoro funleese olopa, Inspekito Nurudeen Thomas fesun lilo omo nilokulo kan.
Inspekito yii ni agbegbe ile awon omobinrin yii ni Thomas to je enjinia ti n ba awon kan kole, ati pe se lomode yii loo sere lodo awon aladugbo won nigba ti iya re jade nile.
Bi Thomas se ri omo yii la gbo pe o tan an wonu ile ti won n ko lowo naa to si fipa ba a lopo.
O ni iwa naa lodi, bee lo si nijiya nla labe ofin iwa odaran tipinle Eko ti odun 2015.
Nigba ti Lekan n wi awijare tire, o ni iro ni won pa mo oun ati pe oro naa pa oun lerin pupo. O ni ojo ti pe tawon dokita akosemose ti so foun pe nnkan omokunrin oun ko lagbara ati pe ko gberi ri latigba toun ti di okunrin.
Gbogbo ebe to n be ile ejo lo ja so pato nitori Inspekito Thomas ni ti won ba fii sile, yoo tun maa tesiwaju ninu iwa naa.
Ninu idajo re, Majistreeti agba naa, Kikelomo Ayeye gba beeli re pelu egberun lona eedegbeta naira pelu oniduro meji ni iye kannaa.
O ni ki won fi faili esun naa ranse si ileese eto idajo ipinle Eko.
Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ojo kokanla osu kewa odun yii.
Friday, 8 September 2017
Home
/
Unlabelled
/
Won ni Lekan fipa ba omokekere sun, lo ba ni "Oluwa mi, nnkan omokunrin mi o le ri"
Won ni Lekan fipa ba omokekere sun, lo ba ni "Oluwa mi, nnkan omokunrin mi o le ri"
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
Sugbon, Oye Ki Adajo pase ayewo fun fun olujejo yi ni lati mo boya otito ni oro e tabi oro ni
ReplyDelete