IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 26 October 2017

Nnkan nla! Gbenga ji oku adiye nile Saka, lo ba foju bale ejo


 Bolaji Akinwale, Osogbo
   
Ko seni to ri Gbenga Daramola ni kootu majistreeti ilu Osogbo ti ko nii mo pe ebi lo sun un dedi iwa to hu.

Gbenga, eni odun mejilelogbon ni won fesun kan pe o ji adiye ti Saka Mojirade ti pa sile, igba to si n sa lo, lowo ba a.

Lara nnkan ti Gbenga tun ji nilee Saka to wa lagbegbe Balogun Biiro, Oke-Baale nilu Osogbo ni ofifo kireeti koka-kola meji, foonu kan pelu aso omode merin.

Ojo ketalelogun osu kesan odun yii ni Inspekito Olayiwola so funle ejo pe Gbenga huwa naa, sugbon nigba ti won koko gbe e lo si kootu, ko lanfaani lati san beeli ti won fun un, idi niyii ti won tun fi gbe e wa si kootu.

Onidajo Fatimah Sodamade waa sun igbejo e siwaju di ogunjo osu kokanla odun yii.

No comments:

Post a Comment