IROYIN YAJOYAJO

Monday, 2 October 2017

Ajo UNICEF ni o ye ki olude wa fawon okunrin tiyawo won ba sese bimo

Tolulope Emmanuel, Osogbo

Ti igbese kan ti ajo United Nations Children’s Fund (UNICEF) fee gbe ba bo sii, iroyin ayo ni yoo je fawon babalomo lagbaye.

Ajo naa ti so laipe yii pe ko si bi obo se se ori ti inaki ko se, won ni bi awon iyalomo lenu ise ijoba se maa n gbolude osu meta leyin ti won ba bimo naa lo ye kawon babalomo naa maa gba.

Asoju ajo naa lorileede yii, Mohammed Fall ni o kere tan, o ye kawon babalomo naa lanfaani si olude ose merin tii se osu kan gbako.

O ni eleyii yoo fun tokotaya lanfaani lati toju omo ti won sese bi ohun daada ko too di pe baba omo yoo pada senu ise.

Mohammed waa ro ijoba ni ekajeka lorileede yii lati gba oro naa yewo ki won si se ohun to to lori e.


No comments:

Post a Comment