IROYIN YAJOYAJO

Monday, 23 October 2017

Akinkanju ni Gani Adams, o to si ipo Aare Ona Kakanfo - Aregbesola


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti ni gbogbo ona ni Otunba Gani Adams fi to si oye Aare ona kakanfo ti Alaafin tilu Oyo, Oba Adeyemi Keta fi je laipe yii.

Nibi ayeye ojoobi adota odun ti okan lara awon oludamoran fun Gomina Aregbesola, Ogbeni Semiu Okanlawon se nilu Iwo laipe yii.

Aregbesola ni akinkanju to ni ife ile Yoruba lokan, paapa ohunkohun to ba nii se pelu oro aabo ile Yoruba.

O ni teeyan ba wo ilu ti Otunba Gani ti jade wa, eeyan a mo pe eni ti kii beru, to si maa n wa isokan ile Yoruba ni.

Aregbesola waa fi da awon eeyan loju pe idagbasoke yoo tun ba iran Yoruba sii lasiko re.


No comments:

Post a Comment