IROYIN YAJOYAJO

Monday, 23 October 2017

Awon akekojade Ilesa Grammar School wo Gomina Aregbesola lo sile ejo


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Agbarijopo egbe awon akekojade ileewe Ilesa Grammar School ti gbe Gomina Rauf Aregbesola lo sile ejo bayii latari bo se taku pe dandan oun yoo yi oruko ileewe naa pada.

Latigba tijoba ti bere sii tun ileewe naa ko la gbo pe ogunlogo awon akekojade nibe ti n pariwo pe ogiri nikan nijoba lee mu atunse ba, kii se oruko.

Sugbon a gbo pe Gomina Aregbesola yari kanle pe afi koun yi oruko ileewe naa pada si Ilesa Government High School eleyii ti ko dun mo awon akekojade naa ninu.

Laipe yii nijoba tun fi iwe ipe ranse sawon akekojade naa labe oruko Ilesa Grammar School Old Students' Association pe ki won farahan nibi ayeye sisi ileewe naa ti yoo waye lola ode yii.

Kia lawon oloye egbe naa kowe pada si gomina pe awon ko lee farahan nibi eto naa. Won ni abamoda gbaa ni oruko tuntun ti gomina fun ileewe naa.

Egbe naa fi kun oro re pe bii igba teeyan mo-on-mo fee tun itan ko nigbese gomina ohun je ati pe bo pe bo ya, otito yoo leke

Amo sa, a gbo pe egbe naa, nipase awon oloye re ti lo sile ejo, okan lara awon akekojade nibe, Agbejoro Wole Olanipekun lagbejoro ti egbe naa fee lo.


No comments:

Post a Comment