IROYIN YAJOYAJO

Friday, 6 October 2017

Alubami la maa na Super Eagles - Wedson Nyirenda

Akonimogba awon egbe agbaboolu orileede Zambia Wedson Nyirenda ti so pe awon ti setan lati gbo ewuro soju awon omo egbe agbabolu Super Eagles ti orileede yii nibi idije ti yoo waye lola. 
Leyin ti awon agbaboolu Zambia tinagije won n je Chipolopolo sedanrawo tan ki won too koja silu Uyo ni Wada soro yii. 
O ni ojo meedogun pere toun darapo mo egbe agbaboolu Zambia ni awon na Super Eagles pelu ayo meji si Eyokan ni Ndola.
Wada ni ko si asiko to to fun awon lati mura fundije naa nigba yen sugbon awon ti gbaradi daada bayii. 
O ni loooto lawon mo pe Eagles kii se eran riro, bee ni awon bowo fun won pupo sugbon awon n lo sinu idije ojoo Satide yii pelu ipinnu okan. 
Idije ola ni eleyii to kangun si asekagba lati mo boya orileede Naijiria yoo Kola ninu idije boolu agbaye ti yoo waye lorileede Russia lodun to n bo.


No comments:

Post a Comment