Tolulope Emmanuel, Osogbo
Omokunrin eni odun merinlelogbon, Oyelami Okeyomi nileese olopa ipinle Osun ti wo lo sile ejo lori esun ipaniyan.
Se la gbo pe 'kinni' Oyelami ko sise latigba to ti dokunrin, idi niyii to fi gba ile babalawo kan lo lojo ketalelogun osu kesan odun yii, nibe ni babalawo ti so fun un pe iyawo-iya e, Alice Okeyomi, eni aadorin odun lo wa nidi adanwo to de ba a.
Oyelami ko kan tie ronu leemeji, se lo sewo si olokada kan to n koja, bi olokada se gbe e dele won lagboole Adigbo nilu Ejigbo lo be sile, o si ni ki olokada duro de oun.
Ariwo oro o ni olokada gbo, bi Oyelami se bo sita ni olokada beere lowo e pe ki lo sele, nigba ti Oyelami si rii pe asiri ti tu lo fese fee sugbon awon araadugbo mu olokada sile nigba ti won rii pe Oyelami ti fi irin fo ori iya naa sinu ile.
Latigba yen ni won ti n wa Oyelami kaakiri ko too di pe owo te e ti won si gbe e wa sile ejo fun esun ipaniyan.
Leyin ti won ka esun re fun un ni adari majistreeti naa, Ashiru Ayeni pase pe ki won loo fi olujejo pamo sogba ewon ilu Ilesa titi di ojo keje osu kokanla tigbejo yoo tun waye lori oro e.
Friday, 6 October 2017
Home
/
iroyin
/
iroyin-kootu
/
isele-nla
/
Kayeefi nilu Ejigbo! Oyelami pa iyawo-iya e, o ni ko je ki 'kinni' oun sise
Kayeefi nilu Ejigbo! Oyelami pa iyawo-iya e, o ni ko je ki 'kinni' oun sise
Tags
# iroyin
# iroyin-kootu
.Unknown
.
isele-nla
Labels:
iroyin,
iroyin-kootu,
isele-nla
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment