IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 17 October 2017

Asiri tu! E ka ohun ti won lo fa a ti olori osise ijoba l'Osun se kowe fipo sile



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Bo tile je pe ijoba ipinle Osun ti so pe se ni asiko ifeyinti lenu ise oba to fun Ogbeni Sunday Olayinka Owoeye to fi kowe ifisesile, sibe arigbamu iroyin ti fidi re mule pe ohun to wa nidi oro naa ju bee lo.

Iwadi fi han pe wahala ohun bere ni nnkän osu meji seyin nigba ti won gbe obinrin kan ti a foruko bo lasiri kuro nileese eto ilera, ti won si gbe e lo sileewosan ijoba kan nilu Osogbo.

Ohun to sele yii la gbo pe o bi obinrin toun naa ti di oga lenu ise naa ninu to fi kowe ifehonuhan si Gomina Aregbesola.

Ninuu leta naa la gbo pe o ti fesun kan olori awon osise oba l'Osun pe se lo fe kawon jo maa se wolewode, o si tun so pe nitori pe oun mo asiri ipasipayo owo to n sele nileese eto ilera ipinle Osun ni won se gbogun ti oun, ti won si gbe oun kuro lofiisi oun.

Oro yii da wahala pupo sile debii wipe awon oga agba bii mefa ni won gbe kuro nileese eto ilera lo sibomiin, ti won si da obinrin ti a n soro re yii pada sofiisi re.

Wahala naa wa peleke sii lasiko ipade awon igbimo alase ipinle Osun ti won se koja, nibe la gbo pe awon komisanna kan ti so oro kobakungbe si Owoeye, eleyi to bii ninu pupo.

O si dabi eni pe se ni olori osise oba yii ro gbogbo e papo pe ko si iwadi kankan lori awon esun ti obinrin ara Ilesa naa fi kan an ti won fi n soro soun sakasaka. Eleyii la gbo pe o see se ko ro papo to fi kowe fipo siłe.

Bakan naa la gbo pe o dabi eni pe tirela ti gba aarin okunrin naa ati Gomina Aregbesola koja, won ni opo igba ni awon agbaagba egbe oselu APC nipinle Osun ti maa n so pe Owoeye ko kunju osunwon ise ti won gbe fun un.
@@@@@@@@@

No comments:

Post a Comment