Tolulope Emmanuel, Osogbo
Ijoba ipinle Osun ti so pe ko si ooto ninu aheso to n lo kaakiri bayii pe awon kan ti n lo kaakiri ipinle Osun bayii lati fun awon omode labere ajesara fun arun ti won n ri lara obo, iyen Monkey Pox.
Ninu atejade kan ti akowe agba fun ajo to n ri si eto ilera alabode nipinle Osun, Dokita Kayode Ogunniyi fi sita salaye pe aheso lasan loro naa.
Ogunniyi ni abere ajesara to n lo lowo laarin ipinle Osun ni eyi to wa fawon omo oojo si odun meji ati pe kii se pe enikeni n gbe e kaakiri rara.
O ni awon ileewosan alabode pelu awon ibudo tijoba ti seto kaakiri lawon omo ti le ri abere naa gba.
Ogunniyi waa fokan awon araalu bale pe ko si arun monkey pox l'Osun, bee ni ko si enikeni to n gbe abere ajesara re ka.
No comments:
Post a Comment