IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 17 October 2017

Eyi ni itan igbesi aye Olowogboyega, olori osise ijoba tuntun l'Osun





Tolulope Emmanuel, Osogbo

Bo tile je pe omobibi ilu Ibokun nijoba ibile Obokun ni Dokita Oyebade Olowogboyega, eni tijoba ipinle Osun yan loniin gege bii olori awon osise ijoba, ilu Orile Owu nijoba ibile Ayedaade ni won bii si lojo kerinlelogun osu keta odun 1962.

O lo sileewe alakobere St. Peter’s Anglican Primary School, Oke-Owu, Orile-Owu laarin odun 1966 si 1973. O koja si The Apostolic Secondary Modern School, Orile-Owu ati Orile-Owu Grammar School laarin odun 1973 ati 1979.

Leyin eyi lo tesiwaju si Local Authority Teacher Training College, Iyana-Offa, Ibadan nipinle Oyo lasiko eto eko odun 1979/80, ko too koja si Adeyemi College of Education, Ondo lodun 1981, o si pari nibe lodun 1984.

Ipinle Borno atijo to ti dipinle Yobe bayii lo ti sinru ilu laarin odun 1984 si 1985.


Ojo kokanla osu kinni odun 1991 lo darapo mo ise ijoba, o bere ise nileese ajo to n mojuto oro awon osise ijoba ibile nipinle Oyo ijoun, o si wa lara awon ti won dari wa sipinle Osun lodun 1991 ti won sedasile re.

Oyebade lo si Obafemi Awolowo University nibi to ti keko gboye ninu imo ofin, to si di agbejoro lodun 2005.

O ti sise kaakiri awon ijoba ibile nipinle Osun ko too de ipo akowe agba lodun 2012.

Oniruuru idanileko lo ti lo lorileede yii ati loke okun. O niyawo, Olorun si fi awon omo rere jinnki igbeyawo naa.

No comments:

Post a Comment