IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 29 October 2017

Awon ara Eko ni won n jere ijoba Aregbesola l'Osun - Fatai Diekola

Tolulope Emmanuel, Osogbo

Okan pataki lara awon asaaju egbe oselu APC nipinle Osun, Alhaji Fatai Diekola ti so gbangba pe ti egbe naa ko ba rowomu ninu idibo gomina to n bo, Gomina Aregbesola ati alaga egbe naa l'Osun, Omooba Gboyega Famodun ni won fa a.

Diekola ni inu n bi awon omo egbe naa gidigidi bayii pelu iwa 'mo gbon tan, mo mo tan' ti Aregbesola n hu, bee ni Famodun naa ko naani ohun to le je atubotan egbe.

O ni ko si imoran kankan to wo awon mejeeji leti, eleyii to si lewu fun egbe naa lopolopo.

Jagun aso, gege bi awon ololufee re se maa n pe, salaye pe awon ara ipinle Eko ni won n jere laala ti awon omo egbe APC Osun n se labe isejoba Aregbesola.

Diekola waa so asotele pe bi ipinya inu egbe naa ba n lo bayii, o see se ki omi ti eyin wo igbin lenu fegbe naa lodun to n bo.



No comments:

Post a Comment