IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 29 October 2017

Leyin odun meta, oku orun fee ba Iyiola Omisore sejo l'Osun


Sinmiloluwa Adigun, Ileefe

Ileese olopa ipinle Osun ti ranse si Seneto Iyiola Omisore bayii lori iwe ifehonuhan kan ti Oloogbe Seneto Isiaka Adetunji Adeleke ko lodun un 2014.

Ninuu leta naa, eleyii ti igbakeji komisanna ileese olopa to wa leka itopinpin iwa odaran, SCIID, Ogbeni Uzochukwu fowosi, ni won ti ni ki Omisore farahan nileese naa lati waa wi tenu e lori esun ti Adeleke fi kan an.

A oo ranti pe lodun naa lohun nigba ti eto idibo gomina ipinle Osun ku feerefe ni wahala be sile laarin awon oludije mejeeji, iyen Omisore ati Adeleke.

Nileetura kan ni Adeleke ti so pe Omisore pelu awon ololufee re gba oun leti, eleyii to pada yori si pentuka laarin won, ti Adeleke si koja sinu egbe oselu APC.

Ohun ti yoo sele bayii peluu bi ileese olopa ipinle Osun tun se hu oro naa jade leyin odun meta, ti eni to si ko iwe esun ti jade laye ni ko ye enikeni.


No comments:

Post a Comment