Tolulope Emmanuel, Osogbo
Ariwo ikunle abiyamo lawon eeyan agbegbe Sabo nilu Ileefe n pa lojoo Tosde to koja nigba ti won ri omobinrin omo odun merindinlogun kan nibi to ti n pokaka iku.
Akeko ni Obafemi Awolowo University ni Mercy Olamide Afolaranmi, ipele akooko leka ti won ti won ti n keko nipa awon nnkan aifojuri (microbiologist) lo si wa.
Ohun ti a gbo ni pe latigba to ti ri esi idanwo to se, to si ni maaki 'E' ninu isee CHM 101 lo ti bere sii kariso, ti ko si ba awon oree re sere mo.
Leyin naa lo ko sorii fasibuuku re pe "Leyin ohun gbogbo, mo fee ri Olorun lojukooju, mo fe ri bo se ri gan an, mi o fee padanu ijoba orun, ki Olorun ran mi lowo".
Afi bo se di ojo Tosde naa ti Olamide po oogun eku mo omi batiri, to si gbe e mu, okan lara awon alajogbele re, Iyaafin Oni lo koko gbo bo se n japoro iku, iyen lo si ta awon araale lolobo, ti won si gbe e lo sileewosan.
Olori awon eso OAU, Babatunde Oyatokun je ka gbo pe bi won se gbo nileewe pe akeko won kan je oogun eku ni won lo sileewosan to wa, won gba adireesi awon obi Olamide lowo e, sugbon ko duro ri awon obi e to fi jade laye.
Ibeere tawon eeyan pelu awon molebi Olamide waa n beere ni pe taa lo pa omodebinrin to ni ojoowaju daada naa, tori won gbagbo pe opolopo lo ni maaki iru eyi to ni sugbon pelu ise asekara, ti won si saseyori jade.
No comments:
Post a Comment