Aminat Sule
Baba agba eni ogota odun kan ti foju bale ejo majistreeti lori esun pe o fipa ba omo re, omo odun mejila lo po.
Yato si pe baba yii, Nuhu Mohammed ba omo re lopo, o tun ki ore omo re toun je omo odun metala lo po.
Ojo ketadinlogun osu kewa yii ni abule Garatu nijoba ibile Bosso nipinle Niger la gbo pe baba yii ti huwa naa leyin to fogbon tan awon omo naa wonuu soobu re.
Nigba to de odo awon olopa, o jewo, bee lo so pe oun jebi esun naa nile ejo.
Majistreeti Fati Auna tile ejo naa waa pase pe ki won loo fi baba naa pamo sogba ewon titi di ojo kerindinlogun osu kokanla tigbejo yoo tun waye lori e.
.
No comments:
Post a Comment