IROYIN YAJOYAJO

Friday, 27 October 2017

Ileefowopamo Skye n gbe ipolongo 'So feeyan, koo je ebun' lo sinu ogba OAU


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Ogba Obafemi Awolowo Yunifasiti yoo mi titi lose to n bo pelu ipolongo oriire ti ileefowopamo Skye n gbe lo sibe.

Ipolongo ohun lo wa lati ta awon akeko lolobo lorii oriire olokanojokan ti won le se lati ara banki naa.

Gege bi adari eka Product and Innovation banki naa, Ogbeni Ndubuisi Osakwe se salaye, akeko to ba ti so fun akeegbe re nipa banki naa, ti onitoun si ni akanti pelu banki Skye yoo gba ebun.

Yato si ebun kekeke, anfaani wa lati je ebun owo to to egberun meedogbon naira si egberun lona aadota naira. Bakan naa ni won tun le je Kia Saloon Car tuntun.

Nibi ipolongo olose kan ohun ni awon osise ileese naa yoo ti salaye nipa SkyeXperience Banking ninu eyi ti awon akeko ti le lo foonu won lati se eto bii fifowo ranse selomiin, sisanwo ina, sisanwo omi ati bee bee lo fawon akeko ohun.

Osakwe waa ro awon akeko lati lo anfaani ipolongo naa daada.


No comments:

Post a Comment