IROYIN YAJOYAJO

Monday, 30 October 2017

Buhari fowo osi juwe ile fun Babachir ati Ayo Oke



Aare orileede yii, Mohammed Buhari ti fowo osi juwe ile fun akowe funjoba apapo orileede yii, Secretary to the government of the Federation, Babachir Lawal David, to si fi Ogbeni Boss Gida Mustapha ropo re.

Bakan naa ni aare pase pe ki olori ajo to n mojuto itopinpin, National Intelligence Agency, Ayo Oke naa maa lo sile.

Osu die seyin ni igbimo kan ti Aare gbe kale lati sewadi awon esun kan ti won fi kan awon mejeeji, eleyii ti igbakeji aare, Ojogbon Osinbajo se alaga re gbe abo iwadi won jade.

Esun ti won fi kan Babachir nigba naa ni pe o fowo si iwe owo kan ninu eyi ti won ti lo milioonu lona igba naira lati ge koriko inu ogba ti won ko awon ti Boko Haramu so di alainile lori si eleyii to wa ni Adamawa.

Ni ti Ayo Oke, awon olofofo kan ni won pariwo fun ajo EFCC pe obitibiti owo ile okeere wa ninu ile e. Latigba naa si ni won ti ni kawon mejeeji loo rookun nile ko too wa di pe ise bo lowo won bayii.

No comments:

Post a Comment