Tolulope Emmanuel, Osogbo
Ileese olopa ipinle Osun ti safihan omokunrin eni odun mokandinlogbon, Kehinde Ariyo lori esun pe o fipa ba iya arugbo eni odun marundinlaadorin lajosepo.
Eemeji otooto la gbo pe Kehinde se 'kinni' funya arugbo naa nile iya ohun to wa lagbegbe Ogudu nilu Ilesa lose to koja.
Koda, konisanna olopa ipinle Osun, Adeoye Fimihan ni se ni iya naa daku rangbondan ti oju-apa lorisiirisii si wa loju araa re.
Kehinde ninu oro tire ni oun ko le salaye bi oro naa se je. O ni ode ariya kan loun ti n bo lojo naa toun fi be iya yen pe ko je koun sun siwaju ita e nitori ile ti su.
O ni nigba ti oju oun wale lojo keji loun too mo nnkan to sele.
No comments:
Post a Comment