Nigerian Association of Women Journalists (NAWOJ), iyen egbe awon obinrin oniroyin lorileede yii, eka tipinle Osun ti yan awon oloye tuntun ti yoo tuko egbe naa fun odun meta.
Nibi eto idibo ohun to waye lolu ile egbe awon oniroyin, eleyii to wa leba Technical nilu Osogbo ni won ti yan Arabinrin Motunrayo Ayegbayo gege bii alaga.
Awon oloye to ku ni Egbedele Bose to je igbakeji alaga, Florence Babasola je akowe, Temitope Olayiwola di igbakeji akowe.
Awon to ku ni Olaide Olowe to di akapo, Folakemi Abe ni akowe isuna, nigba ti Abosede Adebisi di ayewe owo wo.
Alaga egbe oniroyin l'Osun, Comreedi Abiodun Olalere ro awon oloye tuntun naa lati seraa won lokan, ki won si satona isokan laarin awon omo egbe to ku.
Friday, 13 October 2017
Egbe awon oniroyin obinrin l'Osun yan oloye tuntun
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Unknown
.
iroyin-agbegbe
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
Ski yin Ku orire o, aseyori le o se
ReplyDelete