Tolulope Emmanuel, Osogbo
Oro awuyewuye to n waye laarin agbarijopo egbe awon osise ijoba nipinle Osun pelu Gomina Aregbesola lori sisan ekunrere owo osu tun ti gbabomiin yo bayii pelu bi olori awon osise ijoba l'Osun, Ogbeni Olayinka Owoeye se kowe fipo re sile.
Gege bi a ti fi to yin leti tele pe egbe naa fee sepade pajawiri laaro Monde, leyin eyi ti won yoo mu leta gbedeke lo ba Owoeye ninu eyi ti ikilo wa pe tijoba ko ba ti bere sii san ekunrere owo osu fawon, bere latinu osu kejila odun yii, ara ko nii rokun, bee ni ara ko nii ro adiye.
Won sepade ohun loooto, bee ni won mu leta lo soofiisi Owoeye. Lara ohun ti won tun beere ninuu leta naa ni pe kijoba bere sii mu agbega ba awon osise to to si, bee ni ko bere sii sanwo osu nibamu pelu ipele tonikaluku wa.
Sugbon iyalenu lo je pe ojo Monde ohun gan an ni Owoeye kowe fipo sile laiso idi kankan ni pato.
Idi niyii ti opo awon osise ijoba ti a foro wa lenu wo fi n so pe o see se ko je pe latari bi awon egbe osise se hale sinuu leta naa lo da iberubojo sokan Owoeye to fi tete kowe fipo sile.
Bee lawon miin ni o see se ki Owoeye ti fura pe Gomina Aregbesola le ma lanfaani lati se nnkan tawon osise n fe lo fi roo pe ko daa to ki won fi oun joye awodi koun ma si le da asa gbe.
No comments:
Post a Comment