Tolulope Emmanuel, Osogbo
Omokunrin eni odun mokanlelogbon kan, Wakili Ganiyu ti foju bale ejo majistreeti ilu Osogbo lori esun pe o dana sun okada eni ti won jo n gbele.
Gege bi agbenuso funleese olopa, Inspekito Joshua Oladoye se so funle ejo, lojo kerinla osu kewa odun yii ni Ganiyu dede gbe okada Hajue Suzuki to je ti araale re.
Oladoye ni ni nnkan aago kan osan ni Ganiyu huwa naa lagbegbe Odetoyinbo leyin oja Ayegbaju nilu Osogbo.
Owo okada naa, gege bi Oladoye se wi, je egberun lona ogota naira. O ni iwa to hu naa lodi si ofin iwa odaran tipinle Osun.
Iwadi fihan pe se ni Ganiyu fee ta ajoku okada ohun fawon to n ra irin, idi niyii to fi dana sun okada naa.
Wakili, eni ti ko ni agbejoro kankan ni kootu so pe oun jebi awon esun ti won fi kan an.
Ninu idajo re, adajo majistreeti naa, Fatimah Sodamade faaye beeli sile fun un pelu egberun lona aadota naira ati oniduro kan ni iye kannaa.
O waa sun igbejo siwaju di ogunjo osu kokanla odun yii.
No comments:
Post a Comment