Tolulope Emmanuel, Osogbo
Latari ipa to n ko lori oro awon omode, egbe kan ti ko rogboku lejoba, Children of Africa Leadership and Values Development Initiative (CALDEV) ti so Ooni ti Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi di babaasale re bayii.
Lasiko abewo ' e ku ayeye ojoobi' ti egbe naa se si Ojaja Keji laafin re ni eto naa waye.
Gege bi Aare egbe naa, Onorebu Bamidele Salam se so, CALDEV wa lati to awon ogoweere sona nipa ojuse ati ireti ti awujo ni ninuu won nigba ti won ba de ipo adari lorileede yii ati lagbaye.
Salam ni erongba egbe naa tun ni lati pese awon ewe sile, lokan ati lara, lorii awon eto oniruuru ti won ni lawujo pelu bo se je pe awon ni won tete maa n lugbadi oniruuru wahala to ba sele lawujo.
O fi kun oro re pe gbogbo ipa ati owo ife ti Ooni Ogunwusi maa n na sawon omokekeke latigba to ti dori ite awon babanla re lo mu ki egbe naa pinnu lati waa ge keeki ojoobi peluu re, ki won si tun sayeye fun un gege bii babasale egbe CALDEV.
Nigba to n femi imoore han si igbese egbe CALDEV yii, Ooni Ogunwusi ni yoo soro fun orileede to ba ko iyan awon ogoweere kere lati laseyori.
O ni kii dun mo oun ninu toun ba n gbo nipa bi awon kan se maa n fipa mu awon omobinrin kekeke lati lo sile oko laitii tojuu bo.
Oba Adeyeye ni oun yoo lo ipo oun lati daabo bo eto awon ewe lorileede yii. O waa ro tolori telemu lati maa ko awon ewe ni ona to to nitori pe awon ni ogo ojo ola wa.
No comments:
Post a Comment