Tolulope Emmanuel, Osogbo
Pelu bi ajo eleto idibo ijoba ibile nipinle Osun, Osun State Independent Electoral Commission (OSIEC) ti se sekede fawon egbe oselu ti won nife lati kopa ninu eto idibo ijoba ibile ti yoo waye laipe yii lati wa maa forukosile, arigbamu iroyin ti fidi re mule pe egbe oselu merindinlogun ni won ti gbe igbese naa.
Lara awon egbe oselu ti won ti loo forukosile loofiisi ajo naa to wa lopopona Testing Ground l'Osogbo la ti ri Alliance for Democracy, Action Democratic Party, Accord, Action Alliance.
Awon to ku ni All Progressives Congress, Kowa Party, APGA, Democratic People's Party, PPN, UPP, ACD, MPPP, YDP, BNPP, PDM ati NAC.
Ireti wa pe awon egbe oselu ti won ko tii yoju yoo tun lo ko too di ojo kesan osu yii ti ajo OSIEC fun won da.
Iwadi fihan pe ojoo Tosde ose yii ni ajo naa sepade po pelu awon Inter-party Advisory Council nipinle Osun, bakan naa ni won yoo sepade po pelu awon alaga ati akowe egbe oselu ti won ti forukosile loofiisi won loni.
No comments:
Post a Comment