Tolulope Emmanuel, Osogbo
Ilu Osogbo yoo gbalejo awon lookolooko nile yii lojoo Sannde, ojo kejilelogun osu yii nibi ayeye yiyan Oluomo Sunday Akere gege bii Aare kerin fun egbe alaanu ni, International Association of Lions Club ti eka ipinle Osun.
Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ni yoo ko gomina ipinle Ogun ati ti Ondo, Seneto Ibikunle Amosun ati Arakunrin Rotimi Akeredolu sodi lo sibi ayeye naa.
Lojo naa gan an ni egbe ohun l'Osun ti won n pe ni New Era yoo sekowojo fun eto ise abe oju lofe ati rira gilaasi oju fawon ti won nilo re yikaakiri gbogbo ipinle Osun.
Dokita Deji Adeleke ni alaga nibi ayeye naa nigba ti Owa ti Igbajo, Oba Olufemi Fasade yoo je ori ade ojo naa.
Asiwaju Gboyega Awomolo nireti wa pe yoo je baba ojo naa nigba ti Lion Asiwaju Ayebola to je District Governor 404 82 ti egbe naa yoo je olugbalejo agba.
Friday, 6 October 2017
Oluomo Sunday Akere di Aare New Era Lions Club l'Osun
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Unknown
.
iroyin-agbegbe
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment