Adegoke, eni ti gbogbo eeyan mo si K-rad seleri yii ninu oro ikini ku odun to fi ranse salaga awon oluko nipinle Osun fun ti ayeye ojo awon oluko, o ni awon oluko lo ye ko maa gbadun ju lagbaye nitori ise ribiribi ti won n se.
O ni ko si ipo tenikeni le de laye yii laisi iranlowo Olorun nipase awon oluko, idi si niyii ti oun yoo fi mu oro won nibaada toun ba le di gomina ipinle Osun.
Adegoke gboriyin funjoba Gomina Aregbesola fun koriya to n se awon oluko nipinle Osun, o si seleri pe opolopo nnkan meremere loun ti ni nipamo fawon oluko tisejoba oun yoo se lati tun mu nnkan rorun fawon oluko.
O waa ro won lati mase kaare rara ati pe latinu aye yi ni won yoo ti bere sii gbadun gbogbo laala won nitori pe nipase won loun naa ti jeeyan, toun si tun le maa gbero lati di gomina.
No comments:
Post a Comment