IROYIN YAJOYAJO

Friday, 27 October 2017

Iku oro o! Eeyan mefa je amala n'Ibokun, meji ti ku, merin wa losibitu


Bolaji Akinwale, Ilesa

Titi digba ti a n ko iroyin yii jo, ko seni to le so pataki ohun tk sokunfa iku ninu idile kan nilu Ibokun nipinle Osogbo.

Eeyan mefa la gbo pe won je amala dudu ninu idile kan nibe, sugbon nigba ti yoo fi di wakati kan, iya ati omo kan ti jade laye.

Iya to bi obinrin yii naa pelu awon omo meta miin ni won si wa lese kan aye, ese kan orun nileewosan ijoba kan nipinle Osun bayii.

Komisanna feto ilera l'Osun, Isamotu Rafiu fidi isele yii mule.

No comments:

Post a Comment