Tolulope Emmanuel
Okan lara awon oludije to n gbaradi funpo gomina ipinle Osun latinu egbe oselu PDP, Onorebu Kayode Oduoye ti ni isejoba oun yoo seto ayika ti yoofaaye gba oniruuru eto ti yoo mu igbayegbadun ba gbogbo awon eeyan ipinle Osun.
Nibi idanileko kan ti awon akeko nipa amojuto ayika, Faculty of Environmental Design and Nigerian ni Obafemi Awolowo University gbe kale lati fi mo riri Super Kay lo ti soro idaniloju yii.
Oduoye ni ti ayika ba ti see wo daada, kiakia lawon oludasesile yoo maa fi ife han lati wa sipinle Osun, eleyii ti yoo fun oun lanfaani lati mu idagbasoke ti ko legbe ba gbogbo ilu ati igberiko to wa nipinle Osun laiyan ibi kankan niposin.
Oduoye, eni ti Pasito Sam Segun Progress soju fun nibe ro awon odo lati ji kuro loju oorun, ki won mo pe ikawo won ni ojo ola orileede yii wa, ki won bere sii da si oselu.
O ni ipenija nla ni orileede Australlian nibi ti omo odun mokanlelogbon ti di aare laipe yii je fawon odo orileede yii, bee ni ko si nnkan ti ko see se.
Ninu oro idupe oga agba eka naa, Ojogbon M. O. Babalola ni awokose ni Super Kay je fawon odo asiko yii. O waa seleri pe gboingboin lawon wa leyin Oduoye nigbakugba.
No comments:
Post a Comment