IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 17 October 2017

Owongogo eroja buredi ti fee le wa wole o - Egbe oniburedi



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Agbarijopo egbe awon to n se buredi niha Iwo-Oorun Gusu orileede yii ti ro  ijoba apapo lati ba won wa nkan  se si oro bi awon eroja ti won fi  nse buredi se gbenu soke lasiko yii. 

Adari egbe naa, Alhaji Abibu Abolusodun salaye pe oro ise buredi sise lorileede yii ti di eniba laya ko wo o pelu bo se je pe ojoojumo ni owo re nlo soke loja. 

O ni ko seese fun egbe naa  lati fi owo kun owo  buredi nitori oti di ounje fun tolori telemun, egbe naa si je egbe to loju aanu sugbon awon nkerora labe ajaga owongogo eroja tawon n lo.

Ni pataki julo, Alhaji Abolusodun  so pe fulawa tawon nra ni egberun mefa ataabo naira nibere odun yii tidi egberun mokanla ataabo naira bayii. 

Bakannaa lo ni suga tawon nra ni egberun mejo naira tele ti di egberun lona mejidinlogun bayii eleyi to ni o mu un nira fun opolopo omo egbe Masters baker lati sise. 

O ni pupo ninu omo egbe aseburedi ni won ti gbe ilekun soobu won ti latari owongogo awon eroja ti a n lo nitori won ko ri ere kankan je leyin ti won ba ti fi gbogbo owo se buredi tan. 

"A n rawo ebe sijoba apapo lati ba wa mu adinku ba owo fulawa ati suga to je eyi
to po ju ninu nkan ti a n lo kawa naa le rowo hori .

"Awa oniburedi la je sise to mu adinku ba airise se laarin awon odo orileede yii sugbon nibayii ti opolopo wa ti je gbese ko si nnkan ti a le se ju ki  a ti soobu lo, idi si niyii ti awon odo ti ko nise lowo tun se lo si".

No comments:

Post a Comment