IROYIN YAJOYAJO

Monday, 30 October 2017

Isu ogota ni Kehinde ji, ladajo ba ni ko loo lo odun mefa lewon


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Adebayo Kehinde, eni odun metadinlaadota ti owo awon omo ajo Sifu-difensi te nilu Ila Orangun lori esun ole jija ladajo ti ju sewon odun mefa bayii.

Sugbon adajo naa faaye sile fun Kehinde lati san egberun lona ogbon naira gege bii owo itanran.

Inu oko oloko kan la gbo pe Kehinde ti ji isu ogota wa, ti owo si te e, leyin naa ni won fa a le awon omo ajo sifu-difensi lowo.

Won gbe e lo sile ejo lori esun meta to nii se peluu ole jija ati bee bee lo, bee ladajo si pase pe ko lo odun meji meji logba ewon lori esun kookan, eleyii to tumo si pe odub mefa gbako ni yoo lo ayafi to ba ri owo faini re san.

No comments:

Post a Comment