IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 29 October 2017

PDP ni ko je ki n ri owo osu awon osise san o - Aregbesola


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti ni egbe oselu PDP ni eku eda to da wahala ailesanwo osu awon osise sile sorun oun.

Aregbesola ni iwa jegudujera, kiko owo ilu je, sise owo ori epo robi basubasu, eleyii to gbile lasiko isejoba olodun merindinlogun ti egbe oselu PDP lo koba oun.

Lasiko ti Aregbesola n gba awon iko amuseya ijoba apapo lori oro ayelujara lalejo lopin ose lo ti ni ko figba kankan dun mo oun ninu ri pe awon osise ko maa gba owo osu won bo se ye sugbon emi n fe, o se ailera fun ara oun.

Aregbesola fi asiko naa salaye fawon alejo ohun pe ibanilorukoje lasan ni Baba Aafusa ti won n pe oun nitori kii se gbogbo awon osise naa ni won n gba aafusa (half salary).

O waa gboriyin fawon osise ijoba ipinle Osun fun iforiti won pelu ileri pe didun losan yoo so.

No comments:

Post a Comment