Tolulope Emmanuel, Osogbo
Owo ileese olopa ipinle Osun ti te omokunrin kan toruko re n je Rasaki ti gbogbo eeyan mo si Fine Boy eni ti won lo fi majele sinu amala to pa odidi idile kan nilu Ibokun nipinle Osun.
Ose to koja la fi to yin leti pe idile Iyaafin Kehinde Falana nilu Ibokun je amala ati obe gbure tan ni meji ba gbemi mi ninuu won.
Lasiko ti a n ko iroyin yii lowo, eeyan meta la gbo pe o tun ti ku, eleyii to mu un je eeyan marun to ti jepe Olorun nigba ti enikansoso to seku wa lese kan aye ese kan orun.
Sugbon asiri ti tu bayii pe se ni Rasaki n binu si okan lara awon omo iya yen toruko re n je Esther latari pe iyen so pe oun ko fe e mo.
Idi niyii ti Rasaki to n sise okada se ledi apo po mo ore Esther kan to fi dogbon fi majele sinu ounje fundile yen.
Esther ati iya re ni won koko ku, ko too di pe awon meta tun ku sii eleyii ti komisanna feto ilera ipinle Osun ti fidii re mule bayii.
Komisanna funleese olopa l'Osun, Adeoye Olafimihan so pe owo ti te Rasaki ati pe o n ran awon olopa lowo ninu iwadi won bayii.
No comments:
Post a Comment