IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 8 October 2017

Kaabieesi oo! Aregbesola gbe awon marun ga sipo Oba l'Osun



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti fowo sii pe kawon adari ilu marun ti won leto si ade bere sii de e.

Lasiko ipade igbimo alase tipinle Osun ni won ti fenuko lori oro naa.

Gege bi akowe iroyin fun gomina, Ogbeni Sola Fasure se so, awon ti won gba igbega ohun ni Olu ti Ile-Ogbo nijoba ibile Ola Oluwa, Alahun ti Ilahun Ijesa ati Aketewi ti Iketewi Ijesa nijoba Obokun, Alagbede ti Oke Agbede Ijesa ati Likure ti Erinburo Ijesa nijoba ibile ila-oorun Atakunmosa.

Aregbesola waa gbadura pe K’ade pe l’ori, ki bata si pe lese gbogbo won.

No comments:

Post a Comment