Tolulope Emmanuel, Osogbo
Oluwo ti ilu Iwo nipinle Osun, Oba Abdulrasheed Akanbi, Telu 1 ti so pe ajanaku koja mo ri nnkan firi loro awon aseyori ijoba Gomina Aregbesola lori aleefa.
Lasiko ayeye odun keji ti oba yii gun ori ite awon babanla re, eleyii to tun papo pelu ayeye ojobi aadota odun re lo ti salaye pe to ba je pe bi Aregbesola se sise lawon gomina ti won ti koja nipinle Osun naa se ni, ipinle Osun iba ti di apewaawo.
Oba Akanbi ni oun ti lo kaakiri opolopo awon ise akanse tijoba Aregbesola ti se atawon to tun n se lowo, oun si nifokanbale pe awon iran to n bo yoo maa sadura fun gomina ni.
O ni 'idagbasoke ti ko kere lo ti ba ipinle Osun latigba ti Gomina Aregbesola ti dori aleefa, mo si ti foju araa mi ri opolopo awon ise akanse yii, won koja afenuso.
"Aregbesola pin ereje ijoba tiwantiwa kaakiri korokondu ipinle Osun ni, o si ye ni eni to ye kawon eeyan ipinle Osun gboriyin fun, ki won si maa fowosowopo pelu e ko le saseyori dopin "
Monday, 9 October 2017
Ko tii sijoba to dabi ti Gomina Aregbesola - Oluwo
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Unknown
.
iroyin-agbegbe
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment