Busoye Oke, Ekiti
Afaimo ko ma je pe awon olopa ni won yoo pada yanju wahala kan to n lo lowo laarin obinrin abileko kan pelu okunrin kan ti won pe ni wolii nilu Ado-Ekiti.
Orii redio kan ni obinrin naa, Omowale ti n pariwo laipe yii pe woli ijo CAC kan to wa lagbegbe Olokuta nilu Ado-Ekiti lu oun ni jibiti ara pelu ti owo, bee lo ni oun toun torii re se e gan ko so eso rere.
Omowale ni "Ilu Eko ni mo n gbe, aburo mi kan lo ranse si mi pe wolii soosi awon, Olakanye riran si mi ati pe mo maa nilo lati wa si Ado Ekiti fun adura pataki lorii airomobi mi.
"Mo gbaaye lowo okoo mi, won si so pe ki n maa lo. Lojo akooko ti mo debe, Woli Olakanye koko gbadura fun mi ni yara igbalejo, leyin naa lo mu mi wonuu yaara kan nibi to ti gbe gilaasi Sile labe mi eleyii to pe ni ayewo ojuu ara mi.
"Leyin naa lo da nnkan si mi loju ara, owo araa re naa lo si fi ki nnkan naa wonu oju ara mi lo. Bo se seyen tan lo mu mi wonuu baluwe nibi ti mo ti fi ose dudu we lori odo, oun naa si duro ti mi ti mo fi we tan.
"O ni oun maa nilo egberun lona aadota naira, mo si fun un lojo naa, o waa fun mi ni kan bii boolu pe ki n kii soju ara mi ti mo ba ti dele, mo si se bee. Sugbon latigba naa ni n ko ti gbadun oju ara mi mo, egbo adaajinna wa nibe bayii"
Ninu awijare tire, Woli Olakanye ni loooto loun da obinrin naa mo ti oun si gba egberun lona aadota naira lowo e lati seto bi yoo se di olomo laye sugbon o see se ko je pe ko lo nnkan toun ni ko ki soju ara daada boun se palase fun un ni.
Sunday, 8 October 2017
Home
/
iroyin
/
isele-nla
/
"Woli da nnkan soju araa mi, o tun gba owo lowo mi, sibe, n ko romobi, n ko si gbadun" - Omowale
"Woli da nnkan soju araa mi, o tun gba owo lowo mi, sibe, n ko romobi, n ko si gbadun" - Omowale
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment