Tolulope Emmanuel, Osogbo
Lori esun pe o ba igi onigi je, oba alaye kan nipinle Osun, Onigbokiti ti Igbokiti nijoba ibile Egbedore ti foju bale ejo majistreeti bayii.
Oba Sulaiman Oloyede ni won fesun merin otooto to nii se pelu igbimopo huwa buburu, biba nnkan oninnkan je, ati bee bee lo kan.
Agbenuso funleese olopa lori esun naa, Sajenti Rasaq Lamidi salaye funle ejo pe inu osu karun odun yii ni Oba Oloyede eni ogota odun huwa naa.
Barista Akintajuwa to gbenuso fun Oba Oloyede ro ile ejo lati faaye beeli sile fun un lona irorun.
Adajo majistreeti naa, Aisha Oloyade faaye beeli sile fun un pelu milioonu marun naira ati oniduro meji ni iye kannaa.
O waa sun igbejo siwaju di ojo keje osu kejila odun yii.
No comments:
Post a Comment