IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 31 October 2017

Olopa wo gau ! Won sun lo ni tesan, lafurasi ba salo


Meji ninu awon olopa to n sise ni Barracks Police Division to wa ni Surulere nilu Eko ti wo gau bayii latari pe afurasi kan salo mo won lowo lasiko ti won n sun.

Innocent Godswill ni won mu fun esun pe o fipa ba omobinrin eni odun metadinlogun lopo.

Nigba ti owo te e, o bere aisan ninu ago olopa, won si loo toju e nileewosan Randle General Hospital ni Surulere.

Leyin ti araa re ya tan ni won mu un pada sinu akolo awon olopa pelu sekeseke lowo e.

Sugbon se la gbo pe awon olopa ti won wa lenu ise sunlo lale ojo naa ti Innocent fi dogbon jade, to si salo raurau.

Ni bayii, inu wahala nla la gbo pe awon olopa naa wa bayii nitori pe oro ohun ti de etigbo komisanna funleese olopa ipinle Eko, won si ti bere sii sewadi awon olopa toro kan.

No comments:

Post a Comment