Temilade Arewa, Akure
Okan lara awon afurasi adigunjale ti owo ileese olopa ipinle Ondo ba laipe yii ti ni iyawo oun pelu awon molebi e ni won ti oun dedi ole jija.
Omokunrin naa, Chukwuma Okoro so pe egberun lona oodunrun naira ni won beere fun gege bii owo-ori nile ana oun, ko si si bi oun se fee ri owo naa san.
Awon iyoku Okoro ti owo tun ba ni Ezenwa Raphael, Chukwudi Oruma ati Thomas Onofuapo.
Okoro fi kun oro re pe efo loun n ta loja kan nilu Akure ati pe ose meta seyin niyawo oun ti sa kuro nile toun si n be e pe ko pada wa. O ni lati te e lorun loun se pinnu lati loo jale leekan pere.
Alukoro ileese olopa ipinle naa, Femi Joseph ni se ni Okoro loo dena de omobinrin kan to fee lo san owo oja ti won ta to je egberun lona eedegbeta naira si banki lojo naa.
O ni ariwo ti omo naa pa lasiko ti Okoro n lo baagi owo naa mo on lowo lo je kawon ti won wa lagbegbe naa ri Okoro mu.
No comments:
Post a Comment