IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 15 October 2017

Youth Reformers Initiative fee se koriya fawon odo l'Osun


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Egbe kan to wa fun sise iwuri fun awon odo ti won ti laami laaka ninu idawole won lorileede yii, Youth Reformers Initiative ti sagbekale awoodu fawon odo nipinle Osun.

Gege bi Aare egbe naa, Aminat Ajibola O. se salaye, awoodu ohun yoo waye labe eto kan ti won pe ni Osun Youth Ambassador Awards (OYAA).

Eto to je eleekeji iru e ni yoo waye laago kan osan Sannde ojo keedogun osu kewa yii ni Atlantis Civic Center nilu Osogbo.

Aminat fi kun oro re pe awon odo ti won je omobibi ipinle Osun ti won si ti mu igbega ba oruko Osun lenu isee won ni won yoo gba awoodu nibi eto naa.

O ni leyin ayewo finnifinni legbe naa too mu awon odo ti won fee fun lawoodu ohun.

No comments:

Post a Comment