Oloye Olusegun Obasanjo ti ni gbogbo nnkan to ba gba loun yoo fun un lati ri pe oun naa wa lara awon ti yoo darapo mo awon angeli lati maa korin nijoba orun.
Obasanjo, eni to ti figba kan ri je aare orileede yii soro naa lasiko ipade orin tawon egbe akorin ti ijo Apostolic Faith Church gbe kale lagbegbe Igbesa nipinle Ogun.
Obasanjo ni pelu iriri oun nibi ipade orin lojo naa, oun mo pe orin awon angeli yoo tun dun ju bee lo, idi si niyii toun fi pinnu lokan oun pe afi koun dejoba orun.
O ni "a gbodo mura sile fun bibo Jesu leekeji, ko si ariyanjiyan nipa e. Mo ni ore kan to maa n so pe nigba ti a ba ko gbogbo orin tan lorun, ko nii si orin kankan mo, gbogbo re a waa da bii eni pe a wa logba ewon, sugbon pelu bi awon egbe akorin yii se korin loni, o wu mi ki n lo sijoba orun, ki n maa ba awon angeli korin.
"To ba je pe bayii ni iyin Olorun yoo se ri lohun, maa wa nibe, mo fe lati lo si orun rere".
No comments:
Post a Comment