IROYIN YAJOYAJO

Monday, 9 October 2017

Owo olopa te Bosede to n jale l'Osogbo

Tolulope Emmanuel, Osogbo

Ileese olopa ipinle Osun ti wo iyaale ile kan, Bosede Ogunkanmi lo sile ejo lori esun ole jija.

Bosede ni won fesun kan pe o ji owo to din die ni egberun lona ogojo naira to je ti Adewumi Adewusi.

Nnkan aago mokanla owuro ojo kefa osu kewa odun yii ni agbenuso funleese olopa, Inspekito Abiodun Fagboyinbo so pe olujejo huwa naa ninu oja Faridah ni Dada Estate nilu Osogbo.

Olujejo ni oun ko jebi esun kansoso ti won fi kan an, bee naa ni agbejoro re, Yinka Dada ro ile ejo lati gba beeli re

Ninu idajo Majistreeti O.A. Oloyade, o gba beeli olujejo pelu egberun lona igba naira ati oniduro meji ni iye kannaa.

O waa sun igbejo siwaju di ojo kesan osu kokanla odun yii.

No comments:

Post a Comment