Leyin odun mokandinlogun ti eni to je Aare Onaa Kakanfo kerinla nile Yoruba, Oloye Moshood Kashimawo Olawale Abiola jade laye, Alaafin ti ilu Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi Keta ti kede Otunba Gani Adams gege bii eni to to si ipo naa bayii.
Eleyii jeyo ninuu leta kan ti Oba Adeyemi fi ranse si Gani Adams, eni to je adari egbe Odua Peoples Congress (OPC) lorileede yii loni ojo keedogun osu kewa.
Adams, eni to je omobibi ilu Arigidi-Akoko nipinle Ondo, to si tun je olugbelaruge Olokun Foundation ati oludasile Donyx Global Concept ni yoo je Aare Onaa Kakanfo keedogun nile Yoruba.
Awon ti won ti je oye naa seyin niwonyii:
1. Kokoro Gangan of Iwoye
2. Oyapote of Iwoye
3. Oyabi of Ajase
4. Adeta of Jabata
5. Oku of Jabata
6. Afonja of Ilorin
7. Toyeje of Ogbomosho
8. Edun of Gbogun
9. Amepo of Abemo
10. Kurumi of Ijaye
11. Ojo Aburumaku of Ogbomosho (son of Toyeje of Ogbomosho)
12. Latoosa of Ibadan
13. Lakode Akintola of Ogbomosho (Premier of the Western region in the First Republic)
14. MKO Abiola of Abeokuta
Aki Otunba Gani Adams ku orire ipo nla kanka to, ki Olorun duro tiyin o
ReplyDelete