IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 5 October 2017

O ma se o! Awon agbebon seku pa ojogbon kan ni yunifasiti Benin



Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo, inu iberubojo lawon oluko ati akeko University of Benin nipinle Edo wa bayii latari bi awon agbebon se seku pa okan lara awon Ojogbon ileewe naa lale ana.

Ojogbon Paul Otasowie la gbo pe won yinbon pa niwaju Ilee re lopopona Ekehuan nijoba ibile Oredo nipinle Edo nirole ana.

Bi awon kan se n so pe awon adigunjale ni won pa Ojogbon Paul to wa ni eka Electrical and Electronics Engineering nileewe naa lawon kan so pe awon agbenipa ni.

Alukoro ileewe naa, Micheal Osasuyi fidi isele naa mule, o si so pe awon alakoso ko tii le so ni lati bi oro iku Ojogbon ti won sapejuwe gege bii akinkanju naa se je.

No comments:

Post a Comment