Tolulope Emmanuel, Osogbo
Agbarijopo egbe awon odo nilu Modakeke, Modakeke Youth Movement ti ke si Gomina Aregbesola lati mase fi owo yepere mu idunkukulaja awon odo kan latilu Ileefe laipe yii ki omi alaafia to ti wa laarin ilu mejeeji le maa toro sii.
Laipe yii lawon odo kan nileefe, Ife Youth Vanguard ati Great Ife ko leta kan ninu eyi ti won ti so pe Ogunsua ti Modakeke, Oba Francis Adedoyin n tase agere lo sori ile awon ara Ife eleyii ti won lo lodi si adehun alaafia ti ilu mejeeji fowosi lodun 1999.
Awon egbe naa, Ife Youth Vanguard tun so ninuu leta naa pe ti gomina ko ba tete wa nnkan se soro naa, a je pe ere omode lasan ni ogun Modakeke/ Ife to waye laarin odun 1997 si 2001 yoo je.
Sugbon awon odo ilu Modakeke ni tiwon so pe ko si ooto ninu esun ti won fi kan Oba Adedoyin ati pe ko tii si igba kankan tawon eeyan ilu Modakeke tabi oba won se lodi si adehun alaafia odun 1999.
Won ni ti awon odo ilu Ileefe ba ni ohunkohun lati yanju pelu Oba Adedoyin, se lo ye ki won lo sile ejo dipo ki won maa darin ogun kaakiri.
Leta ohun so pe olufe alaafia lawon eeyan ilu Modakeke, bee ni won feran Ooni tilu Ileefe, Oba Adeyeye Ogunwusi daada nitori pe olufe alaafia ni.
Won waa ro Gomina Aregbesola pelu awon eso alaabo lati mase fowo yepere mu ihale naa, ati pe ki won fi pampe ofin gbe gbogbo awon odo ti won fee da omi alaafia ilu mejeeji ru.
No comments:
Post a Comment