IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 18 October 2017

Odaju lawon gomina ti won je awon osise lowo osu - Aare Buhari


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Aare orileede yii, Mohamodu Buhari ti ni ijoloju lo je fun oun pe pelu obitibiti owo iranwo tijoba apapo n fun awon ijoba ipinle, sibe opolopo won lo si je gbese owo osu awon osise.


Aare Buhari ni ohun to tun waa ya oun lenu ju ni bo se rorun fun awon gomina ohun lati maa sun, ki won si maa hanrun nigba ti ebi opagbafowomeke n ba awon osise won finra.


Lasiko abewo ti alaga agbarijopo egbe awon gomina lorileede yii, to tun je gomina ipinle Zamfara, Abdulaziz Abubakar Yari pelu awon gomina kan se sii nile ijoba nilu Abuja ni Aare ti fi aidunnu re han.

O ni oun ko mo idi tawon gomina kan ko fi ni imolara iya to n je awon osise abee won ti won je lowo nitori pe se lara maa n ta oun toun ba ti gbo iye owo osu ti opo won je.

Buhari ni bawo ni osise ti ko gbowo osu se fee bo iyawo atawon omo re, ka too waa so pe yoo wulo lawujo.

O waa ro awon gomina ti won je awon osise lowo osu lati tete wa nnkan se si oro naa pelu ileri pe oun ko nii je ki agara da oun lati tubo maa pese owo ti won yoo fi bo ninu e nipa mimojuto ilana sisanwo sinu asunwon kansoso, iyen Treasury Single Account.

No comments:

Post a Comment