IROYIN YAJOYAJO

Friday, 24 November 2017

Ko si ohun rere kankan to le jade latinu ijoba Buhari - Atiku


Igbakeji aare orileede yii tele, to tun je adari ninu egbe oselu APC, Alhaji Atiku Abubakar ti so pe isejoba Aare Mohamadu Buhari ti ja awon omo orileede yii kule ni gbogbo ona.

Atiku, eni to soro yii ninu atejade kan to gbe jade ninu eyi to fi n dagbere fun egbe oselu APC laaro yii salaye pe olugbala lawon omo orileede yii ro pe o de lasiko ti won n dibo fun Buhari sugbon idakeji loro naa je bayii.

O ni losu kejila odun 2013 lawon agbagba kan ninu egbe oselu APC waa be oun nile pe koun darapo mo won lasiko ti iyapa ti wa ninu egbe PDP, o ni won seleri foun pe ko nii si ojusaju tabi iwa imotara eni nikan ninu egbe naa, sugbon iyalenu lo je fun oun pe nnkan to n sele ninu egbe APC buru ju tinu egbe PDP gan an lo.

Atiku fi kun oro re pe egbe oselu APC ko nigbagbo ninu riro awon odo lagbara rara, idi si niyen to fi je pe kikida awon arugbo lo wa ninu awon omo igbimo alase orileede yii.

O ni oun pinnu lati fi egbe naa sile nitori pe o ti ja awon araalu kule, bee ni ko si le si iyipada kankan titi tijoba yii yoo fi pari. Idi si niyii toun fi pinnu leyin ifikunlukun pelu awon molebi atawon alatileyin oun ninu oselu lati loo tun ero oun pa nipa egbe oselu toun yoo darapo mo.

No comments:

Post a Comment