Tolulope Emmanuel, Osogbo
Laifi ti egbe oselu tonikuluku won wa se, eeyan egberun lona aadota ti won wa kaakiri ekun Iwo-oorun Osun ni ajo kan ti ko rogboku lejoba, Favour, Kindness and Grace Foundation yoo seto iwosan ofe fun lori oniruuru aisan to ba n ba won finra.
Ajo naa, pelu ifowosowopo Omooba Dotun Babayemi nireti wa pe yoo lo kaakiri ilu meedogun to wa lagbegbe naa fun itoju awon aisan bii iba, ibaponju, awon ti oju n yo lenu ati bee bee lo laigba owo kankan lowoo won.
Omooba Babayemi ni lati nnkan odun marun seyin ni ajo naa ti bere ise ribiribi ohun eleyii to je ona lati rii pe awon eeyan oun wa nilera pipe ni gbogbo ona.
O ni ajo naa tun ni ibasepo pelu ileewosan OAUTHC lati le seto ise abe lofe fun awon to nilo re.
Omooba Babayemi fi kun oro re pe opolopo awon eeyan ni ko lanfaani lati maa lo sileewosan lati ro dokita latibere odun titi di opin re sugbon yoo je anfaani nla fun won ti won ba ri enikan gbe iru ooreofe baa lo ka won mole.
Lara awon dokita ti won n sayewo fawon araaalu Gbongan nijoba ibile Ayedaade ti eto naa ti bere, Dokita Celestine Mume so pe eto naa wa lati samojuto ilera awon eeyan agbegbe naa.
Mume waa gboriyin fun ajo naa pelu Omooba Babayemi fun igbese akin ohun eleyii to ni yoo ni ipa rere lori oro eto aje agbegbe naa nitori pe eni to ba wa nilera pipe nikan lo lee sise daada.

No comments:
Post a Comment