IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 4 November 2017

O wu awon eeyan Ileefe ki n di Olori Ooni, sugbon....... - Aralola


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Gbajugbaja obinrin onilu gangan nni, Aralola Olumuyiwa ti so gbangba bayii pe ko si nnkankan laarin oun ati Ooni tilu Ileefe, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi.

O ni aheso lasan lawon eeyan n gbe kaakiri pe o see se koun di Olori laafin Ooni latari bi oro awon mejeeji se yeraa awon.

Latigba ti Olori Ooni tele, Zaynab Otiti ti keru jade laafin la gbo pe awon eeyan ti n gbe aheso kaakiri pe o see se ki ife ikoko wa laarin Ooni ati Aralola toun naa ko si lodo oko to bimo kansoso fun ohun.

Idi niyii ti obinrin ti Ooni fi je Cultural Ambassador fun ilu Ileefe naa fi bo sorii ayelujara lati so pe loooto loun sun mo Ooni, sugbon ko si oro ife laarin awon.

Atupale ohun ti Aralola so lede oyinbo ni pe “Ooto ni pe Olori ni won maa n pe mi ni Ife, awon eeyan gbagbo pe emi lobinrin kabiesi. Awon opo (widows) atawon eeyan kan ti pe mi pe ki n jowo waa di Olori. Won gbagbo pe mo kunju osunwon pelu kabiesi; mo ni imo nipa asa, ede kabiesi si ye mi pupo, a sunmora sugbon otito ibe ni pe kii se kabiesi, bee ni n ko da awon eeyan ti won n so bee lebi rara".

Aralola ni oun ti ni oko miin tawon eeyan yoo mo laipe.


No comments:

Post a Comment