IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 4 November 2017

Taani yoo di alaga apapo egbe oselu PDP ninu awon oludije meteeta yii?




Igbimo abenugan egbe oselu PDP niha Iwo Oorun orileede yii ti kede oruko awon meta ninuu awon ti won n dije funpo alaga apapo egbe naa lati ekun ohun.

Awon meta ohun ni Oloye Olabode George eni to ti figba kan je igbakeji alaga apapo egbe naa, Ojogbon Taoheed Adedoja to je minista foro ere idaraya tele lorileede yii ati Ojogbon Tunde Adeniran, minista tele feto eko.

Ninu atejade kan eleyii ti Alhaji Shuaib Oyedokun to je okan lara awon igbimo apapo egbe naa fowosi salaye pe awon agbaagba egbe yoo gbiyanju lati rii pe awon oludije meteeta naa fa enikansoso sile laarin won ko too di ojo kesan osu kejila tipade apapo egbe naa yoo waye.

Lara awon ti won n dupo naa tele ni Otunba Gbenga Daniel, Jimi Agbaje, Wale Ladipo ati bee bee lo.

No comments:

Post a Comment