Bi kii ba se tawon agbofinro ti won tete fi ero tajutaju le awon odo kan ti won kolu Seneto Dino Melaye nilu Kabba loni, nnkan ti iba sele yoo lagbara pupo.
Ayeye Kabba Day la gbo pe won pe Melaye si, terintoyaya ni won si fi pade e nigba to debe ni nnkan aago mokanla aaro, koda oniruuru awon legbelegbe ni won ba a ya foto.
Nigba to to asiko, o ba awon eryan soro, o si gbe milioonu meta naira kale fundagbasoke ilu naa.
Sugbon oro beyin lo lasiko to fee kuro nibe, se lawon odo kan ti won ti lugo de e fon jade pelu okuta, pio wota, igi, igo, ti won si bere sii ju lu moto G-wagon to gbe lo sibe. Awon agbofinro ti won wa nibe la gbo pe won bere sii ju ero tajutaju titi ti Melaye fi raaye kuro nibe.
Koda, a gbo pe ni kete ti Gomina ipinle Kogi toun naa ti denu ilu Kabba fun ayeye naa gbo nipa ohun to sele si Melaye lo pada lona fun iberu ohun to le sele soun naa.
No comments:
Post a Comment